Deuteronomy 24:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹ bá ti ká èso àjàrà yín, ẹ kò gbọdọ̀ pada sẹ́yìn láti ká àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn àlejò ati àwọn opó ati àwọn aláìní baba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba nká eso ọgbà-àjara rẹ, ki iwọ ki o máṣe peṣẹ́ lẹhin rẹ: ki eyinì ki o jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí o bá kórè èṣo àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.