Deuteronomy 24:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ẹnìkan bá jí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbé, tí ó sì ń lò ó gẹ́gẹ́ bí ẹrú, tabi tí ó tà á, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa olúwarẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe mú ohun burúkú yìí kúrò láàrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi a ba mú ọkunrin kan ti njí ẹnikan ninu awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Israeli, ti o nsìn i bi ẹrú, tabi ti o tà a; njẹ olè na o kú; bẹ̃ni iwọ o mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí a bá mú ọkùnrin kan tí ó jí ọ̀kan nínú arákùnrin rẹ̀ ní Ísírẹ́lì gbé àti tí ó jí ọ̀kan nínú ẹrú tàbí kí ó tàá, ẹni tí ó jí ènìyàn gbé ní láti kú. Ẹní láti wẹ búburú kúrò láàrin yín.