Deuteronomy 24:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú yín, ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá là sílẹ̀ fun yín láti ṣe, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ma kiyesi àrun-ẹ̀tẹ, ki iwọ ki o ṣọra gidigidi ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn alufa awọn ọmọ Lefi yio ma kọ́ nyin: bi emi ti pa a laṣẹ fun wọn, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ma kiyesi lati ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ti àrùn ẹ̀tẹ̀ kíyèsára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ti pàṣẹ fún ọ. O ní láti máa fi ìṣọ́ra tẹ̀lé ohun tí mo ti pa láṣẹ fún wọn.