Deuteronomy 25:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá fun yín ní ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí wọ́n wà ní àyíká yín, ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, pípa ni kí ẹ pa àwọn ará Amaleki run lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kò gbọdọ̀ gbàgbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fun ọ ni isimi lọwọ gbogbo awọn ọtá rẹ yi ọ ká kiri, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní lati ní i, ki iwọ ki o si pa iranti Amaleki rẹ́ kuro labẹ ọrun; iwọ kò gbọdọ gbagbé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí OLÚWA Ọlọ́run yín bá fún un yín ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta yín tí ó yí i yín ká ní ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run ń fi fún yín láti ni ní ìní, ẹ̀yin yóò sì pa ìrántí Ámélékì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Má ṣe gbàgbé.