Deuteronomy 25:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
bí ó bá jẹ́ pé nínà ni ó yẹ kí wọ́n na ẹni tí ó jẹ̀bi, ẹni náà yóo dọ̀bálẹ̀ níwájú adájọ́, wọn yóo sì nà án ní iye ẹgba tí ó bá tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, bi ẹlẹbi na ba yẹ lati nà, ki onidajọ na ki o da a dọbalẹ, ki o si mu ki a nà a ni iye kan li oju on, gẹgẹ bi ìwabuburu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàsán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀.