Deuteronomy 25:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí àwọn arakunrin meji bá jùmọ̀ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan ninu wọn sì kú láìní ọmọkunrin, aya ẹni tí ó kú kò gbọdọ̀ lọ fẹ́ ará ìta tabi àlejò. Arakunrin ọkọ rẹ̀ ni ó gbọdọ̀ ṣú u lópó, kí ó sì máa ṣe gbogbo ẹ̀tọ́ tí ó bá yẹ fún obinrin náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn arakunrin ba ngbé pọ̀, ti ọkan ninu wọn ba si kú, ti kò si lí ọmọkunrin, ki aya okú ki o máṣe ní alejò ara ode li ọkọ: arakunrin ọkọ rẹ ni ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ní i li aya, ki o si ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àwọn arákùnrin rẹ bá jọ ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan wọn sì kú láìní ọmọkùnrin, opó rẹ̀ kò gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ mìíràn tayọ ẹbí ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni yóò mú u ṣe aya, òun ni yóò sì ṣe ojúṣe ọkọ fún un.