Deuteronomy 25:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ọkunrin yìí kò bá wá fẹ́ ṣú aya arakunrin rẹ̀ tí ó kú lópó, obinrin náà yóo tọ àwọn àgbààgbà lọ ní ẹnubodè, yóo sì wí pé, ‘Arakunrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arakunrin rẹ̀ ró ní Israẹli, ó kọ̀ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arakunrin ọkọ mi.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ọkunrin na kò ba si fẹ́ lati mú aya arakunrin rẹ̀, njẹ ki aya arakunrin rẹ̀ ki o gòke lọ si ẹnubode tọ̀ awọn àgba lọ, ki o si wipe, Arakunrin ọkọ mi kọ̀ lati gbé orukọ arakunrin rẹ̀ ró ni Israeli, on kò fẹ́ ṣe iṣẹ arakunrin ọkọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Ísírẹ́lì. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.”