Deuteronomy 25:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, obinrin náà yóo tọ̀ ọ́ lọ lójú gbogbo àwọn àgbààgbà, yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo tutọ́ sí i lójú, yóo sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe sí ẹni tí ó bá kọ̀ láti kọ́ ilé arakunrin rẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni aya arakunrin rẹ̀ yio tọ̀ ọ wá niwaju awọn àgba na, on a si tú bàta rẹ̀ kuro li ẹsẹ̀ rẹ̀, a si tutọ si i li oju; a si dahùn, a si wipe, Bayi ni ki a ma ṣe si ọkunrin na ti kò fẹ́ ró ile arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹṣẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.”