Deuteronomy 26:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ní ọdún kẹtakẹta, tíí ṣe ọdún ìdámẹ́wàá, tí o bá ti dá ìdámẹ́wàá gbogbo ìkórè oko rẹ, kí o kó wọn fún àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, kí wọ́n lè máa jẹ àjẹyó ninu ìlú yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba da idamẹwa asunkun rẹ tán li ọdún kẹta, ti iṣe ọdún idamẹwa, ti iwọ si fi fun ọmọ Lefi, alejò, alainibaba, ati opó, ki nwọn ki o ma jẹ li ẹnubode rẹ, ki nwọn si yó;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí o bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹ́ta sọ́tọ̀ sí apákan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Léfì, àjòjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó.