Deuteronomy 26:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N kò jẹ ninu ìdámẹ́wàá mi nígbà tí mò ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò kó èyíkéyìí jáde kúrò ninu ilé mi nígbà tí mo jẹ́ aláìmọ́, tabi kí n fi èyíkéyìí ninu wọn bọ òkú ọ̀run. Gbogbo ohun tí o wí ni mo ti ṣe, OLUWA Ọlọrun mi, mo sì ti pa gbogbo àṣẹ rẹ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi kò jẹ ninu rẹ̀ ninu ọ̀fọ mi, bẹ̃li emi kò mú kuro ninu rẹ̀ fun ohun aimọ́ kan, bẹ̃li emi kò mú ninu rẹ̀ fun okú: ṣugbọn emi ti gbà ohùn OLUWA Ọlọrun mi gbọ́, emi si ti ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ palaṣẹ fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí OLÚWA Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pa láṣẹ fún mi.