Deuteronomy 26:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní òun óo gbé ọ ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó dá lọ. O óo níyì jù wọ́n lọ; o óo ní òkìkí jù wọ́n lọ, o óo sì lọ́lá jù wọ́n lọ. O óo jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si mu ọ ga jù orilẹ-ède gbogbo lọ ti o dá, ni ìyin, li orukọ, ati ọlá; ki iwọ ki o le ma jẹ́ enia mimọ́ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun sì jẹ́wọ́ pé, òun yóò gbé ọ sókè ju gbogbo orílẹ̀ èdè tí òun ti dá lọ, ní ìyìn, ní òkìkí àti ní ọlá; kí ìwọ kí ó le jẹ́ ènìyàn mímọ́ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí.