Deuteronomy 26:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
mú ninu àkọ́so èso ilẹ̀ náà sinu agbọ̀n kan, kí o sì gbé e lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun rẹ yóo yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o mú ninu akọ́so gbogbo eso ilẹ rẹ, ti iwọ o mú ti inu ile rẹ wá, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ki iwọ ki o si fi i sinu agbọ̀n, ki iwọ ki o si lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèṣè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé.