Deuteronomy 27:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ tí ẹ bá kọjá odò Jọdani, tí ẹ bá ti wọ inú ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ẹ to òkúta ńláńlá jọ kí ẹ fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ́ ti ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o si kó okuta nla jọ, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì sí inú ilẹ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbékalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun.