Deuteronomy 27:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kọ gbogbo òfin wọnyi sára rẹ̀, nígbà tí ẹ bá ń rékọjá lọ láti wọ ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣèlérí fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara wọn, nigbati iwọ ba rekọja; ki iwọ ki o le wọ̀ inu ilẹ na lọ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ, ti ṣe ileri fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí o bá ti ń ré kọjá láti wọ ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ.