Deuteronomy 28:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Àwọn igi eléso rẹ yóo máa so jìnwìnnì ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ búra fún àwọn baba rẹ, pé òun yóo fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA yio si sọ ọ di pupọ̀ fun rere, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu irú ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, ni ilẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ lati fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.