Deuteronomy 28:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA yóo fún ọ ní ọpọlọpọ òjò ní àkókò rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra rẹ̀ lójú ọ̀run, yóo sì bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ìwọ ni o óo máa yá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ní nǹkan, o kò sì ní tọrọ lọ́wọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA yio ṣí iṣura rere rẹ̀ silẹ fun ọ, ọrun lati rọ̀jo si ilẹ rẹ li akokò rẹ̀, ati lati busi iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: iwọ o si ma wín orilẹ-ède pupọ̀, iwọ ki yio si tọrọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò ṣí ọ̀run sílẹ̀, ìṣúra rere rẹ̀ fún ọ, láti rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ ní àsìkò rẹ àti láti bùkún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀ rẹ. Ìwọ yóò yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ṣùgbọ́n ìwọ kò ní í yá lọ́wọ́ ẹnìkankan.