Deuteronomy 28:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Bí o bá ṣe ibi, tí o kọ OLUWA sílẹ̀, ninu gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé, èmi OLUWA yóo da ègún lé ọ lórí, n óo sì mú ìdàrúdàpọ̀ ati wahala bá ọ, títí tí o óo fi parun patapata, láìpẹ́, láìjìnnà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA yio si rán egún, idamu, ati ibawi sori rẹ, ninu gbogbo ohun ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé ni ṣiṣe, titi a o fi run ọ, ati titi iwọ o fi ṣegbé kánkán; nitori buburu iṣe rẹ, nipa eyiti iwọ fi kọ̀ mi silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò rán ègún sóríì rẹ, rúdurùdu àti ìfibú nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ rẹ lé, títí ìwọ yóò fi parun àti wá sí ìparun lójijì nítorí búburú tí o ti ṣe ní kíkọ̀ mi sílẹ̀.