Deuteronomy 28:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo máa pa akọ mààlúù rẹ lójú rẹ, o kò ní fẹnu kàn ninu rẹ̀. Wọn óo fi tipátipá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lọ lójú rẹ, wọn kò sì ní dá a pada fún ọ mọ́. Àwọn aguntan yín yóo di ti àwọn ọ̀tá yín, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn yín lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o si pa akọmalu rẹ li oju rẹ, iwọ ki yio si jẹ ninu rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ rẹ li a o si fi agbara mú lọ kuro li oju rẹ, a ki yio si mú u pada fun ọ wá: a o fi agutan rẹ fun awọn ọtá rẹ, iwọ ki yio si lí ẹniti yio gbà ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Màlúù rẹ yóò di pípa níwájú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ ìkankan nínú rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yóò sì di mímú pẹ̀lú agbára kúrò lọ́dọ̀ rẹ, a kì yóò sì da padà. Àgùntàn rẹ yóò di mímú fún àwọn ọ̀ta rẹ, ẹnìkankan kò sì ní gbà á.