Deuteronomy 28:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin óo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Ẹ óo retí wọn títí, ẹ kò ní gbúròó wọn, kò sì ní sí ohunkohun tí ẹ lè ṣe sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, li a o fi fun enia miran, oju rẹ yio ma wò, yio si su ọ lati ma wò ọ̀na wọn li ọjọ́ gbogbo: ki yio si sí agbara kan li ọwọ́ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ yóò di mímú fún àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, ìwọ yóò sì fi ojú ù rẹ sọ́nà dúró dè wọ́n láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò sì jẹ́ aláìlágbára láti gbé ọwọ́.