Deuteronomy 28:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“OLUWA yóo lé ẹ̀yin ati ẹni tí ẹ bá fi jọba yín lọ sí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa tí wọ́n fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA o mú iwọ, ati ọba rẹ ti iwọ o fi jẹ́ lori rẹ, lọ si orilẹ-ède ti iwọ, ati awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; iwọ o si ma bọ oriṣa nibẹ̀, igi ati okuta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lóríì rẹ lọ sí orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbi ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta.
Recommended Reading