Deuteronomy 28:45 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Gbogbo ègún wọnyi ni yóo ṣẹ si yín lára, tí yóo sì lẹ̀ mọ́ yín pẹ́kípẹ́kí títí tí ẹ óo fi parun, nítorí pé ẹ kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò pa òfin rẹ̀ mọ́, ẹ kò sì tẹ̀lé àwọn ìlànà tí ó pa láṣẹ fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo egún wọnyi yio si wá sori rẹ, yio si lepa rẹ, yio si bá ọ, titi iwọ o fi run; nitoriti iwọ kò fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́ ti o palaṣe fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ègun yìí yóò wá sórí rẹ, wọn yóò lé ọ wọn yóò sì bá ọ títí tí ìwọ yóò fi parun, nítorí ìwọ kò gbọ́ràn sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ, ìwọ kò sì kíyèsí àṣẹ àti òfin tí ó fi fún ọ.