Deuteronomy 28:48 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ní ìhòòhò, pẹlu ebi ati òùngbẹ, ati àìní ni ẹ óo fi máa sin àwọn ọ̀tá tí OLUWA yóo rán si yín, yóo sì la àjàgà irin bọ̀ yín lọ́rùn títí tí yóo fi pa yín run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni iwọ o ṣe ma sìn awọn ọtá rẹ ti OLUWA yio rán si ọ, ninu ebi, ati ninu ongbẹ, ati ninu ìhoho, ati ninu ainí ohun gbogbo: on o si fi àjaga irin bọ̀ ọ li ọrùn, titi yio fi run ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà nínú ebi àti òùngbẹ, nínú ìhòòhò àti àìní búburú, ìwọ yóò sin àwọn ọ̀ta à rẹ tí OLÚWA rán sí ọ. Yóò sì fi àjàgà irin bọ̀ ọ́ ní ọrùn, títí yóò fi run ọ́.