Deuteronomy 28:51 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn yóo jẹ àwọn ọmọ ẹran yín ati èso ilẹ̀ yín títí tí ẹ óo fi parun patapata. Wọn kò ní ṣẹ́ nǹkankan kù fun yín ninu ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín, àwọn ọmọ mààlúù tabi ọmọ aguntan yín; títí tí wọn yóo fi jẹ yín run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si ma jẹ irú ohunọ̀sin rẹ, ati eso ilẹ rẹ, titi iwọ o fi run: ti ki yio kù ọkà, ọti-waini, tabi oróro, tabi ibisi malu rẹ, tabi ọmọ agutan silẹ fun ọ, titi on o fi run ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò jẹ ohun ọ̀sìn rẹ run àti àwọn èṣo ilẹ̀ rẹ títí tí ìwọ yóò fi parun. Wọn kì yóò fi hóró irúgbìn kan fún ọ, wáìnì túntún tàbí òróró, tàbí agbo ẹran màlúù rẹ kankan tàbí ọ̀wọ́ ẹran àgùntàn rẹ títí ìwọ yóò fi run.