Deuteronomy 28:52 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ìlú ńláńlá yín ni wọn óo dó tì, títí tí gbogbo odi gíga tí ẹ gbójúlé, tí ó yí àwọn ìlú ńláńlá yín po, yóo fi wó lulẹ̀, ní gbogbo ilẹ̀ yín. Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní gbogbo ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín ni wọn yóo dó tì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, titi odi rẹ ti o ga ti o si le yio fi wó lulẹ, eyiti iwọ gbẹkẹle, ni ilẹ rẹ gbogbo: on o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, ni gbogbo ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fún ọ.