Deuteronomy 28:53 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ojú yóo pọn yín tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, nígbà tí àwọn ọ̀tá yin bá dó tì yín, tí yóo fi jẹ́ pé àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ni ẹ óo máa pa jẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si jẹ ọmọ inu rẹ, ẹran ara awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ti awọn ọmọ rẹ obinrin ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ninu idótì na ati ninu ihámọ na ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìyà tí ọ̀ta à rẹ yóò fi jẹ ọ́ nígbà ìgbógun tì, ìwọ yóò jẹ, ẹran ara ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí OLÚWA Ọlọ́run ti fi fún ọ.