Deuteronomy 28:55 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní fún ẹnikẹ́ni jẹ ninu ẹran ara ọmọ rẹ̀ tí ó bá ń jẹ ẹ́; nítorí pé kò sí nǹkankan tí ó kù fún un mọ́, ninu ìnira tí àwọn ọ̀tá yín yóo kó yín sí nígbà tí wọ́n ba dó ti àwọn ìlú yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tobẹ̃ ti on ki yio bùn ẹnikan ninu wọn, ninu ẹran awọn ọmọ ara rẹ̀ ti o jẹ, nitoriti kò sí ohun kan ti yio kù silẹ fun u ninu idótì na ati ninu ihámọ, ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìpọ́njú tí àwọn ọ̀ta yóò fi pọ́n ọ lójú ní ìlú u rẹ.