Deuteronomy 28:56 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Obinrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù jùlọ, tí ó sì jẹ́ afínjú jùlọ ninu àwọn obinrin yín, tí kò jẹ́ fi ẹsẹ̀ lásán tẹ ilẹ̀ nítorí àwọ̀ rẹ̀ tí ó tutù ati ìwà afínjú rẹ̀, yóo di ahun sí ọkọ tí ó jẹ́ olùfẹ́ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Obinrin ti awọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, ti kò jẹ daṣa ati fi atẹlẹsẹ̀ rẹ̀ kan ilẹ nitori ikẹra ati ìwa-ẹlẹgẹ́, oju rẹ̀ yio korò si ọkọ õkanaiya rẹ̀, ati si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú u yín, tí ó si ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹṣẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà a rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin