Deuteronomy 28:57 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo bímọ tán, yóo sì jẹ ibi ọmọ tí ó jáde lára rẹ̀ ní kọ̀rọ̀, yóo sì tún jẹ ọmọ titun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, nítorí pé kò sí ohun tí ó lè jẹ mọ́, nítorí àwọn ọ̀tá yín tí yóo dó ti àwọn ìlú yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati si ọmọ-ọwọ rẹ̀ ti o ti agbedemeji ẹsẹ̀ rẹ̀ jade, ati si awọn ọmọ rẹ̀ ti yio bi; nitoripe on o jẹ wọn ni ìkọkọ nitori ainí ohunkohun: ninu ìdótì ati ihámọ na, ti ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí láti inú u rẹ̀ àti àwọn ọmọ tí ó ti bí. Nítorí ó fẹ́ láti jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀ nígbà ìgbógun tì àti ní ìgbà ìpọ́njú tí ọ̀ta rẹ yóò fi jẹ ọ́ nínú àwọn ìlú rẹ.