Deuteronomy 28:64 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA yóo fọ́n yín káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa káàkiri, ati èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati èyí tí wọn fi òkúta ṣe, tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA yio si tu ọ ká sinu enia gbogbo, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; nibẹ̀ ni iwọ o si ma bọ oriṣa ti iwọ ati baba rẹ kò mọ̀ rí, ani igi ati okuta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA yóò fọ́n ọ ká láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀.