Deuteronomy 28:68 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkọ̀ ojú omi ni OLUWA yóo fi ko yín pada sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí mo ti ṣèlérí pé ẹ kò ní pada sí mọ́ lae. Nígbà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ óo fa ara yín kalẹ̀ fún títà gẹ́gẹ́ bí ẹrú, lọkunrin ati lobinrin, ṣugbọn ẹ kò ní rí ẹni rà yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA yio si fi ọkọ̀ tun mú ọ pada lọ si Egipti, li ọ̀na ti mo ti sọ fun ọ pe, Iwọ ki yio si tun ri i mọ́: nibẹ̀ li ẹnyin o si ma tà ara nyin fun awọn ọtá nyin li ẹrú ọkunrin ati ẹrú obinrin, ki yio si sí ẹniti yio rà nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Éjíbítì sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀ta à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́.