Deuteronomy 28:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Yóo bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá tí ó bá dìde sí ọ. Bí wọ́n bá gba ọ̀nà kan dìde sí ọ, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni wọn óo fọ́nká nígbà tí wọn bá ń sálọ fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọ̀na kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọ̀na meje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀ta tí ó dìde sí ọ yóò bì subú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.