Deuteronomy 29:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí ó lè fi ìdí yín múlẹ̀ bí eniyan rẹ̀, kí ó sì máa jẹ́ Ọlọrun yín; gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, ati bí ó ti búra fún Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu àwọn baba ńlá yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o le fi idi rẹ kalẹ li oni li enia kan fun ara rẹ̀, ati ki on ki o le ma ṣe Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ fun ọ, ati bi o ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
láti jẹ́wọ́ rẹ lónìí yìí bí ènìyàn an rẹ̀, pé kí ó lè jẹ́ Ọlọ́run rẹ bí ó ti ṣèlérí àti bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba à rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù.