Deuteronomy 29:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí á má ṣe rí ẹnikẹ́ni ninu yín, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, tabi ìdílé kan, tabi ẹ̀yà kan, tí ọkàn rẹ̀ yóo yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín lónìí, tí yóo sì lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń bọ. Nítorí pé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo dàbí igi tí ń so èso tí ó korò, tí ó sì ní májèlé ninu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnikẹni ki o má ba wà ninu nyin, ọkunrin, tabi obinrin, tabi idile, tabi ẹ̀ya, ti àiya rẹ̀ ṣí kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun wa li oni, lati lọ isìn oriṣa awọn orilẹ-ède wọnyi; ki gbòngbo ti nyọ orõro ati iwọ, ki o má ba wà ninu nyin;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Rí i dájú pé kò sí ọkùnrin tàbí obìnrin, ìdílé tàbí ẹ̀yà láàrin yín lónìí tí ọkàn an rẹ̀ yóò yí kúrò lọ́dọ̀ OLÚWA Ọlọ́run wa láti lọ àtí láti sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè náà; rí i dájú pé kò sí gbòǹgbò tí ó ń mú irú èso kíkan bẹ́ẹ̀ jáde láàrin yín.