Deuteronomy 29:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA kò ní dáríjì olúwarẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ibinu ńlá OLUWA ni yóo bá a. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sinu ìwé yìí yóo ṣẹ sí i lára, OLUWA yóo sì pa orúkọ olúwarẹ̀ rẹ́ kúrò láyé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA ki yio darijì i, ṣugbọn nigbana ni ibinu OLUWA ati owú rẹ̀ yio gbona si ọkunrin na, ati gbogbo egún wọnyi ti a kọ sinu iwé yi ni yio bà lé e, OLUWA yio si nù orukọ rẹ̀ kuro labẹ ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA kì yóò ní ìfẹ́ sí àti dáríjìí; ìbínú àti ìtara rẹ̀ yóò jó ọkùnrin náà. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sínú ìwé yìí yóò wá sórí i rẹ̀, OLÚWA yóò sì yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lábẹ́ ọ̀run.