Deuteronomy 29:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí wọ́n bá rí i tí gbogbo ilẹ̀ náà ti di imí ọjọ́ ati iyọ̀, tí gbogbo rẹ di eérú, tí koríko kankan kò lè hù lórí rẹ̀, bíi ìlú Sodomu ati Gomora, Adima ati Seboimu, tí OLUWA fi ibinu ńlá parẹ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pe gbogbo ilẹ rẹ̀ di imi-õrùn, ati iyọ̀, ati ijóna, ti a kò le gbìn nkan si, tabi ti kò le seso, tabi ti koriko kò le hù ninu rẹ̀, bi ibìṣubu Sodomu, ati Gomorra, Adma, ati Seboiimu, ti OLUWA bìṣubu ninu ibinu rẹ̀, ati ninu ikannu rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ilẹ̀ náà yóò di imí-òórùn, àti iyọ̀, àti ìjóná tí a kò lè fi ọkàn sí, tàbí tí kò lè ṣo èso tàbí tí koríko kò lè hù nínú u rẹ̀, yóò dàbí ìbìṣubú Ṣódómù àti Gòmórà, Ádímà àti Sébóíímù, tí OLÚWA bì subú nínú ìbínú u rẹ̀, àti ìkannú rẹ̀.