Deuteronomy 3:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
(Nítorí pé, Ogu, ọba Baṣani nìkan ni ó kù ninu ìran àwọn Refaimu. Irin ni wọ́n fi ṣe pósí rẹ̀, ó sì wà ní Raba, ní ilẹ̀ àwọn Amoni títí di òní olónìí. Igbọnwọ mẹsan-an ni gígùn pósí náà, ó sì fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin. Igbọnwọ tí ó péye ni wọ́n fi ṣe ìdíwọ̀n pósí náà.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
(Ogu ọba Baṣani nikanṣoṣo li o sá kù ninu awọn omirán iyokù; kiyesi i, akete rẹ̀ jẹ́ akete irin; kò ha wà ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni? igbọnwọ mẹsan ni gigùn rẹ̀, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ni igbọnwọ ọkunrin.)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(Ógù tí í ṣe ọba Báṣánì nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Ráfátì. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rábà ti àwọn Ámórì.)