Deuteronomy 3:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nígbà tí a gba ilẹ̀ náà nígbà náà, àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi ni mo fún, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Anoni ati ìdajì agbègbè olókè ti Gileadi, pẹlu gbogbo àwọn ìlú ńláńlá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ilẹ na yi, ti awa gbà ni ìgbana, lati Aroeri, ti mbẹ lẹba afonifoji Arnoni, ati àbọ òke Gileadi, ati ilu inu rẹ̀, ni mo fi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú àwọn ilẹ̀ tí a gbà ní ìgbà náà, mo fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, ní ilẹ̀ tí ó wà ní àríwá Áréórì níbi odò Ánónì, pọ̀ mọ́ ìdajì ilẹ̀ òkè Gílíádì pẹ̀lú gbogbo ìlú wọn.