Deuteronomy 3:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìdajì tí ó kù lára ilẹ̀ àwọn ará Gileadi, ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Baṣani tíí ṣe ìjọba Ogu, ati gbogbo agbègbè Arigobu, ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Manase.” (Gbogbo ilẹ̀ Baṣani ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ àwọn Refaimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iyokù Gileadi, ati gbogbo Baṣani, ilẹ ọba Ogu, ni mo fi fun àbọ ẹ̀ya Manasse; gbogbo ẹkùn Argobu, pẹlu gbogbo Baṣani. (Ti a ma pè ni ilẹ awọn omirán.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìyókù Gílíádì àti gbogbo Básánì, ní ilẹ̀ ọba Ógù ni mo fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè. (Gbogbo agbégbé Ágóbù ni Básánì tí a mọ̀ sí ilẹ̀ àwọn ará Ráfátì.