Deuteronomy 3:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jairi láti inú ẹ̀yà Manase ni ó gba gbogbo agbègbè Arigobu tí à ń pè ní Baṣani, títí dé etí ààlà ilẹ̀ àwọn Geṣuri, ati ti àwọn Maakati. Ó sọ àwọn ìlú náà ní orúkọ ara rẹ̀; ó pè wọ́n ní Hafoti Jairi. Orúkọ náà ni wọ́n ń jẹ́ títí di òní olónìí.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jairi ọmọ Manasse mú gbogbo ilẹ Argobu, dé opinlẹ Geṣuri ati Maakati; o si sọ wọn, ani Baṣan, li orukọ ara rẹ̀, ni Haffotu-jairi titi, di oni.)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jáérì ọ̀kan nínú àwọn ìran Mánásè gba gbogbo agbégbé Ágóbù títí dé ààlà àwọn ará Gésúrì àti àwọn ará Mákátì; a sọ ibẹ̀ ní orúkọ rẹ̀ torí èyí ni Básánì fi ń jẹ́ Hafoti-Jáírì títí di òní.)