Deuteronomy 3:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ati ilẹ̀ Araba títí kan odò Jọdani. Láti Kinereti títí dé Òkun Araba tí wọn ń pè ní Òkun Iyọ̀, ní ẹsẹ̀ òkè Pisiga ní apá ìlà oòrùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹtẹlẹ̀ ni pẹlu, ati Jordani ati opinlẹ rẹ̀, lati Kinnereti lọ titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, nisalẹ awọn orisun Pisga ni ìha ìla-õrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Apá ìwọ̀ óòrùn rẹ̀ ni Jọ́dánì, ní aginjù, láti Kínérétì títí dé òkun aginjù (Tí í ṣe òkun iyọ̀) ní ihà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.