Deuteronomy 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn OLUWA wí fún mi pé, ‘Má bẹ̀rù rẹ̀, nítorí pé mo ti fi òun ati àwọn eniyan rẹ̀ ati ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, ohun tí o ṣe sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni ni kí o ṣe sí òun náà.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun mi pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe emi ti fi on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀, le ọ lọwọ; iwọ o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù u rẹ̀ torí pé mo ti fi lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀. Bí ẹ tí ṣe sí Ṣíhónì ọba Ámórì, tí ó jọba ní Héṣíbónì ni kí ẹ ṣe sí i.”