Deuteronomy 3:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
títí tí OLUWA yóo fi fún àwọn arakunrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún yín, tí àwọn náà yóo wà lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun wọn ní òdìkejì odò Jọdani. Nígbà náà ni olukuluku yín yóo to pada sórí ilẹ̀ tí mo ti fun yín.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Titi OLUWA o fi fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti fi fun ẹnyin, ati titi awọn pẹlu yio fi ní ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun wọn loke Jordani: nigbana li ẹnyin o pada, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀, ti mo ti fi fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
títí di ìgbà tí OLÚWA yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jọ́dánì. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.”