Deuteronomy 3:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Mo sọ fún Joṣua nígbà náà pé; ‘Ṣé ìwọ náà ti fi ojú ara rẹ rí ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe sí àwọn ọba meji wọnyi? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA yóo ṣe sí ìjọba yòókù tí ẹ óo gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si fi aṣẹ fun Joṣua ni ìgbana, wipe, Oju rẹ ti ri gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ti ṣe si awọn ọba mejeji wọnyi: bẹ̃ni OLUWA yio ṣe si gbogbo ilẹ-ọba nibiti iwọ o kọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Jósúà pé, “Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ.