Deuteronomy 3:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
‘OLUWA Ọlọrun, o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi títóbi ati agbára rẹ han èmi iranṣẹ rẹ ni; nítorí pé, oriṣa wo ló wà, lọ́run tabi láyé yìí tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu bíi tìrẹ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA Ọlọrun, iwọ ti bẹ̀rẹsi fi titobi rẹ hàn fun iranṣẹ rẹ, ati ọwọ́ agbara rẹ: nitoripe Ọlọrun wo ni li ọrun ati li aiye, ti o le ṣe gẹgẹ bi iṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi iṣẹ-agbara rẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọlọ́run Alágbára, ìwọ tí ń fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ. Ọlọ́run wo ló tó bẹ́ẹ̀ láyé àti lọ́run tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tí o ti ṣe?