Deuteronomy 3:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gun orí òkè Pisiga lọ, gbé ojú sókè, kí o sì wo apá ìwọ̀ oòrùn, ati apá àríwá, ati apá gúsù, ati apá ìlà oòrùn. Ojú ni o óo fi rí i, nítorí pé, o kò ní kọjá odò Jọdani yìí sí òdìkejì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gùn ori òke Pisga lọ, ki o si gbé oju rẹ soke si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù, ati si ìha ìla-õrùn, ki o si fi oju rẹ wò o: nitoripe iwọ ki yio gòke Jordani yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gòkè lọ sí orí òkè Písígà, sì wò yíká ìwọ̀ oòrùn, ìlà oòrun, àríwá àti gúúsù. Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jọ́dánì yìí.