Deuteronomy 3:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn pàṣẹ fún Joṣua, mú un lọ́kàn le, kí o sì kì í láyà; nítorí pé, òun ni yóo ṣiwaju àwọn eniyan wọnyi lọ, tí wọn yóo fi gba ilẹ̀ tí o óo rí.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn fi aṣẹ fun Joṣua, ki o si gbà a niyanju, ki o si mu u li ọkàn le: nitoripe on ni yio gòke lọ niwaju awọn enia yi, on o si mu wọn ni ilẹ na ti iwọ o ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n yan Jósúà, kí o sì gbà á níyànjú, mú un lọ́kàn le, torí pé òun ni yóò ṣíwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọjá, yóò sì jẹ́ kí wọn jogún ilẹ̀ náà tí ìwọ yóò rí.”