Deuteronomy 30:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí gbogbo àwọn ibukun tabi ègún tí mo gbé kalẹ̀ níwájú yín lónìí bá ṣẹ mọ́ yín lára, tí ẹ bá dé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí, tí ẹ bá ranti anfaani tí ẹ ti sọnù,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
YIO si ṣe, nigbati gbogbo nkan wọnyi ba dé bá ọ, ibukún ati egún, ti mo filelẹ niwaju rẹ, ti iwọ o ba si ranti ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ ṣíwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrin àwọn orílẹ̀ èdè,