Deuteronomy 30:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ bí mo ti fun yín lónìí, tí ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin, ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì máa pọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà tí yóo sì di tiyín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li eyiti mo palaṣẹ fun ọ li oni lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀ mọ́, ki iwọ ki o le yè, ki o si ma bisi i, ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le busi i fun ọ ni ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí mo pàṣẹ fún ọ lónìí láti fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, láti rìn ní ọ̀nà a rẹ̀ àti láti pa àwọn àṣẹ, ìpinnu àti òfin rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni ìwọ yóò máa gbé tí o ó sì máa pọ̀ sí i, OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò bùkún ọ ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.