Deuteronomy 30:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo fi ilẹ̀ ati ọ̀run ṣe ẹlẹ́rìí níwájú yín lónìí, pé mo fun yín ní anfaani láti yan ikú tabi ìyè, ati láti yan ibukun tabi ègún. Nítorí náà, ẹ yan ìyè kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè wà láàyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi pè ọrun ati ilẹ jẹri tì nyin li oni pe, emi fi ìye ati ikú, ibukún ati egún siwaju rẹ: nitorina yàn ìye, ki iwọ ki o le yè, iwọ ati irú-ọmọ rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lónìí mo pe ọ̀run àti ayé bí ẹlẹ́rìí sí ọ pé mo ti gbékalẹ̀ síwájú rẹ ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún. Nísinsìnyìí yan ìyè, nítorí kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lè gbé