Deuteronomy 30:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀, kí ẹ sì máa súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè pẹ́ láyé, kí ẹ sì lè máa gbé orí ilẹ̀ tí OLUWA búra láti fún àwọn baba yín, àní Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o le ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ki iwọ ki o le ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ati ki iwọ ki o le ma faramọ́ ọ: nitoripe on ni ìye rẹ, ati gigùn ọjọ́ rẹ: ki iwọ ki o le ma gbé inu ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, ati fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí ìwọ sì lè fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, fetí sílẹ̀ sí ohùn un rẹ̀, kí o sì dúró ṣinṣin nínú rẹ̀. Nítorí OLÚWA ni ìyè rẹ, yóò sì fún ọ ní ọdún púpọ̀ ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fi fún àwọn baba rẹ Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.